47Nígbà tí Hadadi sì kú, Samla láti Masreka, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
48Samla sì kú, Saulu ti Rehoboti létí odò sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
49Nígbà tí Saulu kú, Baali-Hanani, ọmọ Akbori jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
50Nígbà tí Baali-Hanani kú, Hadadi ni ó jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Pau; orúkọ ìyàwó sì ni Mehetabeeli ọmọbìnrin Matiredi, ọmọbìnrin Mesahabu.
51Hadadi sì kú pẹ̀lú. Àwọn baálẹ̀ Edomu ni: baálẹ̀ Timna, baálẹ̀ Alfa, baálẹ̀ Jeteti