31Beti-Markaboti Hormah; Hasari Susimu, Beti-Biri àti Ṣaraimi. Àwọn wọ̀nyí ni ìlú wọn títí di ìgbà ọba Dafidi,
32agbègbè ìlú wọn ni Etamu, Aini, Rimoni, Tokeni, Aṣani àwọn ìlú márùn-ún,
33àti gbogbo ìletò wọn, tí ó wà yí ìlú náà ká, dé Baali. Àwọn wọ̀nyí ni ibùgbé wọn. Àti ìtàn ìdílé wọ́n.
34Meṣobabu àti Jamleki, Josa ọmọ Amasiah,
35Joẹli, Jehu ọmọ Josibiah, ọmọ Seraiah, ọmọ Asieli,