1 Samuẹli 30

Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti ẹgbẹ̀ta (600) ọmọkùnrin tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wá sí ibi àfonífojì Besori, apá kan sì dúró.

1 Samuel 30:9 (UKJV) So David went, he and the six hundred men that were with him, and came to the brook Besor, where those that were left behind stayed.

7Dafidi sì wí fún Abiatari àlùfáà, ọmọ Ahimeleki pé, èmí bẹ̀ ọ́, mú efodu fún mi wá níhìn-ín yìí. Abiatari sì mú efodu náà wá fún Dafidi.

8Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa wí pé, “Kí èmi ó lépa ogun yìí bi? Èmi lè bá wọn?” Ó sì dá a lóhùn pé, “Lépa, nítorí pé ni bíbá ìwọ yóò bá wọn, ni gbígbà ìwọ yóò sì rí wọn gbà.”

9Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti ẹgbẹ̀ta (600) ọmọkùnrin tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wá sí ibi àfonífojì Besori, apá kan sì dúró.

10Ṣùgbọ́n Dafidi àti irinwó (400) ọmọkùnrin lépa wọn: igba ènìyàn tí àárẹ̀ mú, tiwọn kò lè kọjá odò Besori sì dúró lẹ́yìn.

11Wọ́n sì rí ará Ejibiti kan ní oko, wọ́n sì mú un tọ Dafidi wá, wọ́n sì fún un ní oúnjẹ, ó sì jẹ; wọ́n sì fún un ní omi mu.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.