14Nígbà náà Hasaeli fi Eliṣa sílẹ̀ ó sì padà sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí Beni-Hadadi béèrè, “Kí ni ohun tí Eliṣa sọ fún ọ?” Hasaeli dá a lóhùn, “Ó sọ fún mi wí pé ìwọ yóò sàn nítòótọ́.”
15Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì ó mú aṣọ tí ó nípọn, ó sì kì í bọ inú omi ó sì tẹ̀ ẹ́ sí ojú ọba, bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú. Nígbà náà Hasaeli sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
16Ní ọdún karùn-ún ti Joramu ọmọ Ahabu ọba Israẹli, nígbà tí Jehoṣafati jẹ́ ọba Juda, Jehoramu ọmọ Jehoṣafati bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Juda.
17Ó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́jọ.
18Ó sì rìn ní ọ̀nà ọba Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu ti lọ, nítorí ó fẹ́ ọmọbìnrin Ahabu ó sì ṣe ohun búburú níwájú Olúwa.