1Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin màlúù Baṣani lórí òkè Samaria, ẹ̀yin obìnrin tí ó ń ni tálákà lára, tí ó ń tẹ aláìní mọ́lẹ̀, tí ó wí fún ọkọ rẹ̀, “Gbé wá kí a sì mu!”
2Olúwa Olódùmarè ti fi ìwà mímọ́ rẹ̀ búra: “Àkókò náà yóò dé nítòótọ́ nígbà tí a ó fi ìwọ̀ mú un yín lọ, ẹni tí ó kẹ́yìn pẹ̀lú ìwọ̀ ẹja.
3Ẹni kọ̀ọ̀kan yín yóò jáde lọ gba àárín odi yíya a ó sì lé e yín sí Harmoni,” ni Olúwa wí.
4“Ẹ lọ sí Beteli láti dẹ́ṣẹ̀; ẹ lọ sí Gilgali kí ẹ sì dẹ́ṣẹ̀ sí i. Ẹ mú ẹbọ sísun yín láràárọ̀ wá, ìdámẹ́wàá yín ní ọdọọdún mẹ́ta.