2“Wúńdíá Israẹli ṣubú láì kò sì le padà dìde ó di ẹni ìkọ̀tì ní ilẹ̀ rẹ̀ kò sí ẹni tí yóò gbé e dìde.”
3Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “Ìlú tí ẹgbẹ̀rún (1,000) alágbára ti jáde, yóò dín ku ọgọ́rùn-ún ní Israẹli. Ìlú tí ọgọ́rùn-ún alàgbà ti jáde yóò ṣẹ́kù ẹni mẹ́wàá.”
4Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ilé Israẹli: “Wá mi kí o sì yè;
5ẹ má ṣe wá Beteli, ẹ má ṣe lọ sí Gilgali, ẹ má ṣe rìnrìn àjò lọ sí Beerṣeba. Nítorí dájúdájú a ó kó Gilgali ní ìgbèkùn, A ó sì sọ Beteli di asán.”
6Ẹ wá Olúwa, ẹ̀yin yóò sì yè, kí ó má ba à gbilẹ̀ bí iná ní Josẹfu a sì jó o run Beteli kò sì ní rí ẹni tí yóò bu omi pa á.