Amosi 9

“Ní ọjọ́ náà ní Èmi yóò gbé àgọ́ Dafidi tí ó wó ró, Èmi yóò dí odi rẹ̀ tí ó ya, Èmi yóò sì gbé ahoro rẹ̀ sókè, Èmi yóò sì kọ bí ti ọjọ́ ìgbàanì,

Amos 9:11 (UKJV) In that day will I raise up the tabernacle of David that is fallen, and close up the breaches thereof; and I will raise up his ruins, and I will build it as in the days of old:

9“Nítorí Èmi yóò pàṣẹ, Èmi yóò sì mi ilé Israẹli ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè bí a ti ń jọ nǹkan nínú ajọ̀ tí hóró kín ń kín kì yóò bọ́ sórí ilẹ̀.

10Gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn mi ni yóò ti ipa idà kú gbogbo àwọn ti ń wí pé, ‘Aburú kì yóò lé wa bá, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ká wa mọ́.’

11“Ní ọjọ́ náà ní Èmi yóò gbé àgọ́ Dafidi tí ó wó ró, Èmi yóò dí odi rẹ̀ tí ó ya, Èmi yóò sì gbé ahoro rẹ̀ sókè, Èmi yóò sì kọ bí ti ọjọ́ ìgbàanì,

12kí wọn le jogún ìyókù Edomu àti gbogbo àwọn kèfèrí, ti a ń pè nípa orúkọ mi,” ni Olúwa, ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí.

13“Ọjọ́ náà ń bọ,” ni Olúwa wí, “tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè bá. Tí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn bá. Àwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀, tí yóò sì sàn láti ara àwọn òkè kéékèèké.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.