12Sọkún síta, kí ó sì pohùnréré ẹ̀kún, ọmọ ènìyàn, nítorí yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi; yóò wá sórí gbogbo ọmọ-aládé Israẹli ìbẹ̀rù ńlá yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi nítorí idà náà; nítorí náà lu oókan àyà rẹ.
13“ ‘Ìdánwò yóò dé dandan. Tí ọ̀pá aládé Juda èyí tí idà kẹ́gàn, kò bá tẹ̀síwájú mọ́ ń kọ́? Ni Olúwa Olódùmarè wí.’
14“Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́. Jẹ́ kí idà lu ara wọn lẹ́ẹ̀méjì, kódà ní ẹ̀ẹ̀mẹta. Ó jẹ́ idà fún ìpànìyàn idà fún ìpànìyàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀, tí yóò sé wọn mọ́ níhìn-ín àti lọ́hùnnún.
15Kí ọkàn kí ó lè yọ́ kí àwọn tí ó ṣubú le pọ̀, mo ti gbé idà sí gbogbo bodè fún ìparun. Háà! A mú kí ó kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná, a gbá a mú fún ìparun.
16Ìwọ idà, jà sí ọ̀tún kí o sì jà sí òsì lọ ibikíbi tí ẹnu rẹ bá dojúkọ.