9“ ‘Ní ọjọ́ náà oníṣẹ́ yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde nínú ọkọ̀ ojú omi láti dẹ́rùbà Kuṣi tí ó wà nínú àlàáfíà. Ìrora yóò wá sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ìparun Ejibiti. Kíyèsi i, ó dé.
10“ ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Èmi yóò mú òpin bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn Ejibiti láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli.
11Òun àti àwọn ológun rẹ̀ ẹ̀rù àwọn orílẹ̀-èdè ní a o mú wá láti pa ilẹ̀ náà run. Wọn yóò fa idà wọn yọ sí Ejibiti ilẹ̀ náà yóò sì kún fún àwọn tí a pa.
12Èmi yóò mú kí àwọn odò Naili gbẹ, Èmi yóò sì ta ilẹ̀ náà fún àwọn ènìyàn búburú: láti ọwọ́ àwọn àjèjì ènìyàn, Èmi yóò jẹ́ kí ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tí ó wá nínú rẹ ṣòfò. Èmi Olúwa ni ó ti sọ ọ́.
13“ ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Èmi yóò pa àwọn òrìṣà run, Èmi yóò sì mú kí òpin dé bá ère gbígbẹ́ ni Memfisi. Kò ní sí ọmọ-aládé mọ́ ní Ejibiti, Èmi yóò mú kí ìbẹ̀rù gba gbogbo ilẹ̀ náà.