5Nítorí nípa Ẹ̀mí àwa ń fi ìgbàgbọ́ dúró de ìrètí òdodo.
6Nítorí nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà; ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ti ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́.
7Ẹ̀yin ti ń sáré dáradára. Ta ni dí yin lọ́wọ́ láti ṣe ìgbọ́ràn sí òtítọ́?
8Ìyípadà yìí kò ti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó pè yín wá.
9Ìwúkàrà díẹ̀ ní í mú gbogbo ìyẹ̀fun wú.