1Àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Habakuku rí.
2Olúwa, èmi yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi? Tàbí kígbe sí ọ ní ti, “Ìwà ipá!” Ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà?
3Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédéé? Èéṣe tí ìwọ sì fi ààyè gba ìwà ìkà? Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi; ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú.
4Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí, ìdájọ́ òdodo kò sì borí. Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká, nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà.