Isaiah 33

Gbogbo okùn rẹ ni ó ti dẹ̀: Ìgbókùnró kò fìdímúlẹ̀, wọn kò taṣọ agbọ́kọ̀rìn, lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógun ni a ó pín àní arọ pẹ̀lú yóò ru ìkógun lọ.

Isaiah 33:23 (UKJV) Your tacklings are loosed; they could not well strengthen their mast, they could not spread the sail: then is the prey of a great spoil divided; the lame take the prey.

21Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti jẹ́ alágbára kan fún wa. Yóò sì dàbí ibi àwọn odò ńlá ńlá àti odò kéékèèké. Kì yóò sí ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú tí yóò kọjá lórí i wọn, ọkọ̀ ojú omi ńlá ni a kì yóò tù lórí wọn.

22Nítorí Olúwa ni onídàájọ́ wa, Olúwa ni onídàájọ́ wa, Olúwa òun ni ọba wa; òun ni ẹni tí yóò gbà wá là.

23Gbogbo okùn rẹ ni ó ti dẹ̀: Ìgbókùnró kò fìdímúlẹ̀, wọn kò taṣọ agbọ́kọ̀rìn, lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógun ni a ó pín àní arọ pẹ̀lú yóò ru ìkógun lọ.

24Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ń gbé Sioni tí yóò wí pé, “Ara mi kò yá,” a ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀ jì wọ́n.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.