Jeremiah 12

Àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn ìdílé ti dà ọ́, kódà wọ́n ti kẹ̀yìn sí ọ, wọ́n ti hó lé ọ lórí. Má ṣe gbà wọ́n gbọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ dáradára.

Jeremiah 12:6 (UKJV) For even your brethren, and the house of your father, even they have dealt treacherously with you; yea, they have called a multitude after you: believe them not, though they speak fair words unto you.

4Yóò ti pẹ́ tó tí ọ̀gbẹlẹ̀ yóò fi wà, tí gbogbo ewéko igbó sì ń rọ? Nítorí àwọn ènìyàn búburú ni ó ń gbé ibẹ̀. Àwọn ẹranko àti àwọn ẹyẹ ti ṣègbé, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ènìyàn ń sọ pé, “Kò lè rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa.”

5Bí ìwọ bá ń bá ẹlẹ́ṣẹ̀ sáré, tí àárẹ̀ sì mú ọ, báwo ni ìwọ yóò ṣe bá ẹṣin díje? Bí ìwọ bá kọsẹ̀ ní ilẹ̀ àlàáfíà, bí ìwọ bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé, kí ni ìwọ ó ṣe nínú ẹkùn odò Jordani?

6Àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn ìdílé ti dà ọ́, kódà wọ́n ti kẹ̀yìn sí ọ, wọ́n ti hó lé ọ lórí. Má ṣe gbà wọ́n gbọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ dáradára.

7Èmi yóò kọ ilé mi sílẹ̀, èmi yóò fi ìní mi sílẹ̀. Èmi yóò fi ẹni tí mo fẹ́ lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.

8Ogún mi ti rí sí mi bí i kìnnìún nínú igbó. Ó ń bú ramúramù mọ́ mi; nítorí náà mo kórìíra rẹ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.