13Kọrin sí Olúwa! Fi ìyìn fún Olúwa! Ó gba ẹ̀mí àwọn aláìní lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.
14Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi! Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má ṣe di ti ìbùkún.
15Ègbé ni fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún baba mi, tí ó mú kí ó yọ̀, tí ó sì sọ wí pé, “A bí ọmọ kan fún ọ—ọmọkùnrin!”
16Kí ọkùnrin náà dàbí ìlú tí Olúwa gbàkóso lọ́wọ́ rẹ̀ láìkáàánú Kí o sì gbọ́ ariwo ọ̀fọ̀ ní àárọ̀, ariwo ogun ní ọ̀sán.
17Nítorí kò pa mí nínú, kí ìyá mi sì dàbí títóbi ibojì mi, kí ikùn rẹ̀ sì di títí láé.