Jeremiah 23

Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ má ṣe fi etí sí àsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wòlíì èké ń sọ fún un yín. Wọ́n ń kún inú ọkàn yín pẹ̀lú ìrètí asán. Wọ́n ń sọ ìran láti ọkàn ara wọn, kì í ṣe láti ẹnu Olúwa.

Jeremiah 23:16 (UKJV) Thus says the LORD of hosts, Hearken not unto the words of the prophets that prophesy unto you: they make you vain: they speak a vision of their own heart, and not out of the mouth of the LORD.

14Àti láàrín àwọn wòlíì Jerusalẹmu, èmi ti rí ohun búburú. Wọ́n ṣe panṣágà, wọ́n sì ń ṣèké. Wọ́n fún àwọn olùṣe búburú ní agbára, tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnìkan tí ó yípadà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀. Gbogbo wọn dàbí Sodomu níwájú mi, àti àwọn ènìyàn olùgbé rẹ̀ bí Gomorra.”

15Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí ní ti àwọn wòlíì: “Èmi yóò mú wọn jẹ oúnjẹ kíkorò, wọn yóò mu omi májèlé nítorí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jerusalẹmu ni àìwà-bí-Ọlọ́run ti tàn ká gbogbo ilẹ̀.”

16Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ má ṣe fi etí sí àsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wòlíì èké ń sọ fún un yín. Wọ́n ń kún inú ọkàn yín pẹ̀lú ìrètí asán. Wọ́n ń sọ ìran láti ọkàn ara wọn, kì í ṣe láti ẹnu Olúwa.

17Wọ́n ń sọ fún àwọn tí ó ń gàn mí pé, ‘Olúwa ti wí pé, ẹ̀yin ó ní àlàáfíà.’ Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn tí ó rìn nípa agídí ọkàn rẹ̀ pé, ‘Kò sí ìpalára kan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí yín.’

18Ṣùgbọ́n èwo nínú wọn ni ó dúró nínú ìgbìmọ̀ Olúwa láti rí i tàbí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ta ni ó gbọ́ tí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ náà?

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.