Jeremiah 23

Wò ó, afẹ́fẹ́ Olúwa yóò tú jáde pẹ̀lú ìbínú à fẹ́ yíká ìjì yóò fẹ́ sí orí àwọn olùṣe búburú.

Jeremiah 23:19 (UKJV) Behold, a whirlwind of the LORD is gone forth in fury, even a grievous whirlwind: it shall fall grievously upon the head of the wicked.

17Wọ́n ń sọ fún àwọn tí ó ń gàn mí pé, ‘Olúwa ti wí pé, ẹ̀yin ó ní àlàáfíà.’ Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn tí ó rìn nípa agídí ọkàn rẹ̀ pé, ‘Kò sí ìpalára kan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí yín.’

18Ṣùgbọ́n èwo nínú wọn ni ó dúró nínú ìgbìmọ̀ Olúwa láti rí i tàbí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ta ni ó gbọ́ tí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ náà?

19Wò ó, afẹ́fẹ́ Olúwa yóò tú jáde pẹ̀lú ìbínú à fẹ́ yíká ìjì yóò fẹ́ sí orí àwọn olùṣe búburú.

20Ìbínú Olúwa kì yóò yẹ̀ títí tí yóò sì fi mú èrò rẹ̀ ṣẹ, ní àìpẹ́ ọjọ́, yóò yé e yín yékéyéké.

21Èmi kò rán àwọn wòlíì wọ̀nyí síbẹ̀ wọ́n lọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn. Èmi kò tilẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀, síbẹ̀ wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.