Jeremiah 4

Nípa ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin àti àwọn tafàtafà gbogbo ìlú yóò sálọ. Ọ̀pọ̀ sálọ sínú igbó; ọ̀pọ̀ yóò sì gun orí àpáta lọ. Gbogbo ìlú náà sì di ahoro; kò sì ṣí ẹnìkan nínú rẹ̀.

Jeremiah 4:29 (UKJV) The whole city shall flee for the noise of the horsemen and bowmen; they shall go into thickets, and climb up upon the rocks: every city shall be forsaken, and not a man dwell therein.

27Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Gbogbo ìlú náà yóò sì di ahoro, síbẹ̀ èmi kì yóò pa á run pátápátá.

28Nítorí náà, ayé yóò pohùnréré ẹkún àwọn ọ̀run lókè yóò ṣú òòkùn nítorí mo ti sọ, mo sì ti pète rẹ̀ mo ti pinnu, n kì yóò sì yí i padà.”

29Nípa ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin àti àwọn tafàtafà gbogbo ìlú yóò sálọ. Ọ̀pọ̀ sálọ sínú igbó; ọ̀pọ̀ yóò sì gun orí àpáta lọ. Gbogbo ìlú náà sì di ahoro; kò sì ṣí ẹnìkan nínú rẹ̀.

30Kí ni ò ń ṣe, ìwọ tí o ti di ìjẹ tán? Ìwọ ìbá wọ ara rẹ ní aṣọ òdodo kí o sì fi wúrà ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́. Àwọn olólùfẹ́ rẹ kẹ́gàn rẹ; wọ́n sì ń lépa ẹ̀mí rẹ.

31Mo gbọ́ ìró kan bí i igbe obìnrin tó ń rọbí, tí ó ń rọbí, ìrora bí i abiyamọ ọmọbìnrin Sioni tí ń pohùnréré ẹkún ara rẹ̀. Tí ó na ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì wí pé, “Kíyèsi i mo gbé, nítorí a ti fi ẹ̀mí mi lé àwọn apani lọ́wọ́.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.