22Ariwo ogun wà ní ilẹ̀ náà ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìparun ńlá.
23Báwo ni ó ṣe fọ́, tí ó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ tó, lọ́wọ́ òòlù gbogbo ayé! Báwo ní Babeli ti di ahoro ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè.
24Mo dẹ pàkúté sílẹ̀ fún ọ ìwọ Babeli, kí o sì tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, o ti kó sínú rẹ̀. A mú ọ nítorí pé o tako Olúwa.
25Olúwa ti kó àwọn ohun èlò ìjà rẹ̀ jáde, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun ti ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Babeli.
26Ẹ wá sórí rẹ̀ láti òpin gbogbo, sí ilé ìṣúra rẹ̀ sílẹ̀, ẹ kó o jọ bí òkìtì ọkà, kí ẹ sì yà á sọ́tọ̀ fún ìparun, ẹ má ṣe fí yòókù sílẹ̀ fún un.