Jeremiah 8

Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mi, rẹ̀wẹ̀sì nínú mi.

Jeremiah 8:18 (UKJV) When I would comfort myself against sorrow, my heart is faint in me.

16Ìró ìfọn imú ẹṣin àwọn ọlọ̀tẹ̀ là ń gbọ́ láti Dani, yíyan àwọn akọ ẹṣin mú gbogbo ilẹ̀ wárìrì. Wọ́n wá láti pa ilẹ̀ náà run, gbogbo ohun tó wà níbẹ̀, ìlú náà àti gbogbo olùgbé ibẹ̀.

17“Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró sí àárín yín, paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa oró wọn, yóò sì bù yín jẹ,” ni Olúwa wí.

18Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mi, rẹ̀wẹ̀sì nínú mi.

19Fetí sí ẹkún àwọn ènìyàn mi láti ilẹ̀ jíjìnnà wá: “Olúwa kò ha sí ní Sioni bí? Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni?” “Èéṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère wọn, pẹ̀lú àwọn òrìṣà àjèjì tí wọn kò níláárí?”

20“Ìkórè ti rékọjá, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti parí, síbẹ̀ a kò gbà wá là.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.