34Láti tẹ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà.
35Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá-ògo jùlọ,
36láti yí ìdájọ́ ènìyàn padà, ǹjẹ́ Olúwa kò rí ohun bẹ́ẹ̀.
37Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀ tí Olúwa kò bá fi àṣẹ sí i.
38Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá-ògo jùlọ ni rere àti búburú tí ń wá?