55Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa, láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò.
56Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, “Má ṣe di etí rẹ sí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.”
57O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́, o sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù.”
58Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò, o ra ẹ̀mí mi padà.
59O ti rí i, Olúwa, búburú tí a ṣe sí mi. Gba ẹjọ́ mi ró!