Lefitiku 13

Bí ó bá ràn ká awọ ara, kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́. Ààrùn tí ó ń ràn ni èyí.

Leviticus 13:22 (UKJV) And if it spread much abroad in the skin, then the priest shall pronounce him unclean: it is a plague.

20Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ó bá jinlẹ̀ ju awọ ara rẹ̀ lọ tí irun tirẹ̀ sì ti di funfun, kí àlùfáà pe ẹni náà ni aláìmọ́. Ààrùn ara tí ó le ràn ló yọ padà lójú oówo náà.

21Bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò tí kò sì sí irun funfun níbẹ̀ tí ó sì ti gbẹ, kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje.

22Bí ó bá ràn ká awọ ara, kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́. Ààrùn tí ó ń ràn ni èyí.

23Ṣùgbọ́n bí ojú ibẹ̀ kò bá yàtọ̀, tí kò sì ràn kára, èyí jẹ́ àpá oówo lásán, kí àlùfáà pe ẹni náà ni mímọ́.

24“Bí iná bá jó ẹnìkan tí àmì funfun àti pupa sì yọ jáde lójú egbò iná náà.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.