19ti ìdílé Joiaribu, Mattenai; ti ìdílé Jedaiah, Ussi;
20ti ìdílé Sallu, Kallai; ti ìdílé Amoki, Eberi;
21ti ìdílé Hilkiah, Haṣabiah; ti ìdílé Jedaiah, Netaneli.
22Àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Lefi ní ìgbà ayé Eliaṣibu, Joiada, Johanani àti Jaddua, àti pẹ̀lú ti àwọn àlùfáà ni a kọ sílẹ̀ ní ìgbà ìjọba Dariusi ará Persia.
23Àwọn olórí ìdílé láàrín àwọn ọmọ Lefi títí di àkókò Johanani ọmọ Eliaṣibu ni a kọ sílẹ̀ nínú ìwé ìtàn.