13láti inú ẹ̀yà Aṣeri, Seturu ọmọ Mikaeli.
14láti inú ẹ̀yà Naftali, Nabi ọmọ Fofsi;
15láti inú ẹ̀yà Gadi, Geueli ọmọ Maki.
16Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ènìyàn tí Mose rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. (Hosea ọmọ Nuni ni Mose sọ ní Joṣua.)
17Nígbà tí Mose rán wọn lọ láti yẹ ilẹ̀ Kenaani wò, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà gúúsù lọ títí dé àwọn ìlú olókè.