12Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti gbéra wọ́n sì pa ibùdó ní àfonífojì Seredi.
13Láti ibẹ̀ lọ, wọn ṣí, wọ́n sì dó sí ìhà kejì Arnoni, tí ó wà ní aginjù tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ àwọn ọmọ Amori. Arnoni jẹ́ ààlà fún ilẹ̀ Moabu, láàrín Moabu àti Amori.
14Ìdí nìyìí tí ìwé ogun Olúwa se wí pé, “…Wahebu ní Sufa, Òkun Pupa àti ní odò Arnoni
15àti ní ìṣàn odò tí ó darí sí ibùjókòó Ari tí ó sì fi ara ti ìpínlẹ̀ Moabu.”
16Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ rìn dé Beeri, èyí ni kànga tí Olúwa sọ fún Mose, “Kó àwọn ènìyàn jọ èmi ó sì fún wọn ní omi.”