26Àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Seredi, ìdílé Seredi; ti Eloni, ìdílé Eloni; ti Jaleeli, ìdílé Jaleeli.
27Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (60,500).
28Àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; Manase àti Efraimu.
29Àwọn ọmọ Manase: ti Makiri, ìdílé Makiri (Makiri sì bí Gileadi); ti Gileadi, ìdílé àwọn ọmọ Gileadi.
30Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gileadi: ti Ieseri, ìdílé Ieseri; ti Heleki, ìdílé Heleki