35Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: láti ọ̀dọ̀ Ṣutelahi, ìdílé àwọn ọmọ Ṣutelahi; ti Bekeri, ìdílé àwọn ọmọ Bekeri; ti Tahani, ìdílé àwọn ọmọ Tahani.
36Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ṣutelahi: ti Erani, ìdílé àwọn ọmọ Erani.
37Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Efraimu, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (32,500). Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.
38Àwọn ọmọ Benjamini gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn nìyìí: tí Bela, ìdílé àwọn ọmọ Bela; ti Aṣbeli, ìdílé àwọn ọmọ Aṣbeli; ti Ahiramu, ìdílé àwọn ọmọ Ahiramu;
39ti Ṣufamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣufamu; ti Hufamu, ìdílé àwọn ọmọ Hufamu.