38Àwọn ọmọ Benjamini gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn nìyìí: tí Bela, ìdílé àwọn ọmọ Bela; ti Aṣbeli, ìdílé àwọn ọmọ Aṣbeli; ti Ahiramu, ìdílé àwọn ọmọ Ahiramu;
39ti Ṣufamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣufamu; ti Hufamu, ìdílé àwọn ọmọ Hufamu.
40Àwọn ọmọ Bela ní ipasẹ̀ Ardi àti Naamani nìyìí: ti Ardi, ìdílé àwọn ọmọ Ardi; ti Naamani, ìdílé àwọn ọmọ Naamani.
41Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Benjamini; gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; àti àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé ẹgbẹ̀jọ (45,600).
42Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Ṣuhamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu. Wọ̀nyí ni ìdílé Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.