20Olóòtítọ́ ènìyàn yóò rí ìbùkún gbà gan an ṣùgbọ́n ẹni tí ojú ń kán láti di ọlọ́rọ̀ kì yóò lọ láìjìyà.
21Ojúsàájú ṣíṣe kò dára, síbẹ̀ ènìyàn kan ń ṣẹ̀ nítorí òkèlè oúnjẹ kan.
22Ahun ń sáré àti là kò sì funra pé òsì dúró de òun.
23Ẹni tí ó bá ènìyàn kan wí yóò rí ojúrere ni nígbẹ̀yìn ju ẹni tí ó ní ètè ẹ̀tàn lọ.
24Ẹni tí ó ja baba tàbí ìyá rẹ̀ lólè tí ó sì wí pé, “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀,” irú kan ni òun àti ẹni tí ń pa ni run.