5Nítorí ohùn ìkérora mi, egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran-ara mi.
6Èmi dàbí ẹyẹ igún ní ijù: èmi dàbí òwìwí ibi ahoro.
7Èmi dìde; èmi dàbí ẹyẹ lórí ilé.
8Ní ọjọ́ gbogbo, àwọn ọ̀tá ológoṣẹ́ mi ń gàn mí; àwọn tí ń ṣe ìkanra sí mi ń fi orúkọ mi bú.
9Èmi jẹ eérú gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ mi, èmi sì da ohun mímu mi pọ̀ pẹ̀lú omijé.