Saamu 44

Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntàn, Ìwọ sì ti tú wa ká sí àárín àwọn kèfèrí.

Psalm 44:11 (UKJV) You have given us like sheep appointed for food; and have scattered us among the heathen.

9Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá, Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ-ogun wa jáde mọ́.

10Ìwọ ti bá wa jà, ìwọ sì ti ṣẹ́gun wa níwájú àwọn ọ̀tá wa, àwọn ọ̀tá wa ti gba ilẹ̀ wa, wọ́n sì fi ipá gba oko wa.

11Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntàn, Ìwọ sì ti tú wa ká sí àárín àwọn kèfèrí.

12Ìwọ ta àwọn ènìyàn rẹ fún owó kékeré, Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n.

13Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa, ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.