13Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa, ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.
14Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa.
15Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́, ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,
16nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní ojú àwọn ọ̀tá àti olùgbẹ̀san.
17Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa, síbẹ̀ àwa kò gbàgbé rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mú rẹ̀.