5Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá, kí o sì ràn wá lọ́wọ́, kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là.
6Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀: “Ní ayọ̀, èmi ó pọ Ṣekemu jáde èmi ó sì wọ́n àfonífojì Sukkoti.
7Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase; Efraimu ni àṣíborí mi, Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.
8Moabu ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi, lórí Edomu ní mo bọ́ bàtà mi sí; lórí Filistia ni mo kígbe ayọ̀.”
9Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì? Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Edomu?