Saamu 68

Àwọn akọrin wà ní iwájú, àwọn olórin wà lẹ́yìn; àwọn ọmọbìnrin tí ń lu ṣaworo sì wà pẹ̀lú wọn.

Psalm 68:25 (UKJV) The singers went before, the players on instruments followed after; among them were the damsels playing with timbrels.

23kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó le pọ́n ní inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá rẹ, àti ahọ́n àwọn ajá rẹ ní ìpín tiwọn lára àwọn ọ̀tá rẹ.”

24Wọ́n ti rí ìrìn rẹ, Ọlọ́run, ìrìn Ọlọ́run mi àti ọba mi ní ibi mímọ́ rẹ̀.

25Àwọn akọrin wà ní iwájú, àwọn olórin wà lẹ́yìn; àwọn ọmọbìnrin tí ń lu ṣaworo sì wà pẹ̀lú wọn.

26Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ní ẹgbẹgbẹ́; àní fún Olúwa ẹ̀yin tí ó ti orísun Israẹli wá.

27Níbẹ̀ ní ẹ̀yà kékeré Benjamini wà, tí ó ń darí wọn, níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Juda, níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Sebuluni àti tí Naftali.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.