10Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọn wọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
11Wọ́n wí pé, “Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀? Ọ̀gá-ògo ha ní ìmọ̀ bí?”
12Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyí, ènìyàn asán, wọ́n ń pọ̀ ní ọrọ̀.
13Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́; nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀.
14Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu; a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀.