5Elusai, Jerimoti, Bealiah, Ṣemariah àti Ṣefatia ará Harufiti;
6Elkana, Iṣiah, Asareeli, Joeseri àti Jaṣobeamu ará Kora;
7àti Joẹla, àti Sebadiah àwọn ọmọ Jerohamu láti Gedori.
8Díẹ̀ lára àwọn ará Gadi yà sọ́dọ̀ Dafidi ní ibi gíga ní aginjù. Wọ́n sì jẹ́ onígboyà ológun tí ó múra fún ogun tí ó sì lágbára láti di asà àti ẹṣin mú. Ojú wọn sì dàbí ojú kìnnìún, wọ́n sì yára bí àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè.
9Eseri sì jẹ́ ìjòyè, Obadiah sì jẹ́ igbákejì akọgun, Eliabu ẹlẹ́ẹ̀kẹta,