18Àwọn ọmọ Isari: Ṣelomiti sì ni ẹni àkọ́kọ́.
19Àwọn ọmọ Hebroni: Jeriah sì ni ẹni àkọ́kọ́, Amariah sì ni ẹni ẹ̀ẹ̀kejì, Jahasieli sì ni ẹ̀ẹ̀kẹ́ta àti Jekameamu ẹ̀ẹ̀kẹrin.
20Àwọn ọmọ Usieli: Mika ni àkọ́kọ́ àti Iṣiah ẹ̀ẹ̀kejì.
21Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi. Àwọn ọmọ Mahili: Eleasari àti Kiṣi.
22Eleasari sì kú pẹ̀lú àìní àwọn ọmọkùnrin: Ó ní ọmọbìnrin nìkan. Àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n, àwọn ọmọ Kiṣi, sì fẹ́ wọn.