16Àwọn ọmọ Gerṣomu: Ṣubaeli sì ni alákọ́kọ́.
17Àwọn ọmọ Elieseri: Rehabiah sì ni ẹni àkọ́kọ́. Elieseri kò sì tún ní ọmọ mìíràn, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Rehabiah wọ́n sì pọ̀ níye.
18Àwọn ọmọ Isari: Ṣelomiti sì ni ẹni àkọ́kọ́.
19Àwọn ọmọ Hebroni: Jeriah sì ni ẹni àkọ́kọ́, Amariah sì ni ẹni ẹ̀ẹ̀kejì, Jahasieli sì ni ẹ̀ẹ̀kẹ́ta àti Jekameamu ẹ̀ẹ̀kẹrin.
20Àwọn ọmọ Usieli: Mika ni àkọ́kọ́ àti Iṣiah ẹ̀ẹ̀kejì.