5Asariah ọmọ Natani ni olórí àwọn agbègbè; Sabudu ọmọ Natani, àlùfáà àti olùgba ọba ní ìmọ̀ràn;
6Ahiṣari ni olùtọ́jú ààfin; Adoniramu ọmọ Abida ni ó ń ṣe olórí iṣẹ́-ìlú.
7Solomoni sì tún ní ìjòyè méjìlá lórí gbogbo agbègbè Israẹli, tí wọ́n ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Olúkúlùkù ní láti pèsè fún oṣù kan ní ọdún.
8Orúkọ wọn ni wọ̀nyí: Bene-Huri ní ìlú olókè Efraimu.
9Bene-Dekeri ní Makasi, Ṣaalbimu, Beti-Ṣemeṣi, àti Eloni Beti-Hanani;