1 Samuẹli 30

Ó sì rán an sí àwọn tí ó wà ni Beteli àti sí àwọn tí ó wà ní gúúsù tí Ramoti, àti sí àwọn tí ó wà ní Jattiri.

1 Samuel 30:27 (UKJV) To them which were in Bethel, and to them which were in south Ramoth, and to them which were in Jattir,

25Láti ọjọ́ náà lọ, ó sì pàṣẹ, ó sì sọ ọ di òfin fún Israẹli títí di òní yìí.

26Dafidi sì padà sí Siklagi, ó sì rán nínú ìkógun náà si àwọn àgbàgbà Juda, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ni ẹ̀bùn fún un yín, láti inú ìkógun àwọn ọ̀tá Olúwa wa.”

27Ó sì rán an sí àwọn tí ó wà ni Beteli àti sí àwọn tí ó wà ní gúúsù tí Ramoti, àti sí àwọn tí ó wà ní Jattiri.

28Àti sí àwọn tí ó wà ní Aroeri, àti sí àwọn tí ó wà ní Sifimoti, àti sí àwọn tí ó wà ni Eṣitemoa.

29Àti si àwọn tí ó wà ni Rakeli, àti sí àwọn tí ó wà ní ìlú àwọn Jerahmeeli, àti sí àwọn tí ó wà ni ìlú àwọn ará Keni,

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.