23Dafidi sì wí pé, “Ẹ má ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ara mi: Olúwa ni ó fi nǹkan yìí fún wa, òun ni ó sì pa wá mọ́, òun ni ó sì fi ẹgbẹ́ ogun ti ó dìde sí wa lé wa lọ́wọ́.
24Ta ni yóò gbọ́ tiyín nínú ọ̀ràn yìí? Ṣùgbọ́n bi ìpín ẹni tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ si ìjà ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ìpín ẹni ti ó dúró ti ẹrù; wọn ó sì pín in bákan náà.”
25Láti ọjọ́ náà lọ, ó sì pàṣẹ, ó sì sọ ọ di òfin fún Israẹli títí di òní yìí.
26Dafidi sì padà sí Siklagi, ó sì rán nínú ìkógun náà si àwọn àgbàgbà Juda, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ni ẹ̀bùn fún un yín, láti inú ìkógun àwọn ọ̀tá Olúwa wa.”
27Ó sì rán an sí àwọn tí ó wà ni Beteli àti sí àwọn tí ó wà ní gúúsù tí Ramoti, àti sí àwọn tí ó wà ní Jattiri.