Amosi 5

Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹkún yóò wà ní àwọn òpópónà igbe ìnira yóò sì wà ní àwọn gbàgede ìlú. A ó kó àwọn àgbẹ̀ jọ láti sọkún àti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ láti pohùnréré ẹkún.

Amos 5:16 (UKJV) Therefore the LORD, the God of hosts, the LORD, says thus; Wailing shall be in all streets; and they shall say in all the highways, Alas! alas! and they shall call the farmer to mourning, and such as are skilful of lamentation to wailing.

14Wá rere, má ṣe wá búburú kí ìwọ ba à le yè. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun yóò wà pẹ̀lú rẹ. Òun yóò sì wà pẹ̀lú rẹ bí ìwọ ṣe wí.

15Kórìíra búburú kí o sì fẹ́ rere dúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́ bóyá Olúwa Ọlọ́run alágbára yóò síjú àánú wo ọmọ Josẹfu tó ṣẹ́kù.

16Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹkún yóò wà ní àwọn òpópónà igbe ìnira yóò sì wà ní àwọn gbàgede ìlú. A ó kó àwọn àgbẹ̀ jọ láti sọkún àti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ láti pohùnréré ẹkún.

17Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ọgbà àjàrà, nítorí èmi yóò la àárín yín kọjá,” ni Olúwa wí.

18Ègbé ni fún ìwọ tí ó pẹ́ nítorí ọjọ́ Olúwa kí ni ìwọ fi pẹ́ fún ọjọ́ Olúwa? Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn ní ojú ọjọ́.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.