Oniwaasu 3

Mo ti rí àjàgà tí Ọlọ́run gbé lé ọmọ ènìyàn.

Ecclesiastes 3:10 (UKJV) I have seen the travail, which God has given to the sons of men to be exercised in it.

8ìgbà láti ní ìfẹ́ àti ìgbà láti kórìíra ìgbà fún ogun àti ìgbà fún àlàáfíà.

9Kí ni òṣìṣẹ́ jẹ ní èrè nínú wàhálà rẹ̀?

10Mo ti rí àjàgà tí Ọlọ́run gbé lé ọmọ ènìyàn.

11Ó ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àsìkò tirẹ̀, ó sì ti fi èrò nípa ayérayé sí ọkàn ọmọ ènìyàn, síbẹ̀, wọn kò le ṣe àwárí ìdí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.

12Mo mọ̀ wí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ju pé kí inú wọn dùn kí wọn sì ṣe rere níwọ̀n ìgbà tí wọ́n sì wà láààyè.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.