Oniwaasu 8

Ta ni ó dàbí ọlọ́gbọ́n ènìyàn? Ta ni ó mọ ìtumọ̀ ohun gbogbo? Ọgbọ́n a máa mú ojú ènìyàn dán ó sì máa ń pààrọ̀ ìrínisí rẹ̀.

Ecclesiastes 8:1 (UKJV) Who is as the wise man? and who knows the interpretation of a thing? a man's wisdom makes his face to shine, and the boldness of his face shall be changed.

1Ta ni ó dàbí ọlọ́gbọ́n ènìyàn? Ta ni ó mọ ìtumọ̀ ohun gbogbo? Ọgbọ́n a máa mú ojú ènìyàn dán ó sì máa ń pààrọ̀ ìrínisí rẹ̀.

2Mo sọ wí pé, pa òfin ọba mọ́, nítorí pé, ìwọ ti ṣe ìbúra níwájú Ọlọ́run.

3Má ṣe jẹ́ kí ojú kán ọ láti kúrò ní iwájú ọba, má ṣe dúró nínú ohun búburú, nítorí yóò ṣe ohunkóhun tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.