3Ẹ má ṣe dáná kankan ní ibùgbé yín ní ọjọ́ ìsinmi.”
4Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ.
5Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún Olúwa ní ti: “wúrà, fàdákà àti idẹ;
6aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára; àti irun ewúrẹ́;
7awọ àgbò tí a kùn ní pupa àti awọ màlúù; odò igi kasia;