Eksodu 8

Wọ́n sì kó wọn jọ ni òkìtì òkìtì gbogbo ilẹ̀ sì ń rùn.

Exodus 8:14 (UKJV) And they gathered them together upon heaps: and the land stank.

12Lẹ́yìn tí Mose àti Aaroni tí kúrò ní iwájú Farao, Mose gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sókè sí Olúwa nípa àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí ó ti rán sí Farao.

13Olúwa sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose tí béèrè. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ sì kú nínú ilé àti ní ìta, gbangba àti nínú oko.

14Wọ́n sì kó wọn jọ ni òkìtì òkìtì gbogbo ilẹ̀ sì ń rùn.

15Ṣùgbọ́n ni ìgbà tí Farao rí pé ìtura dé, ó sé ọkàn rẹ̀ le kò sì fetí sí Mose àti Aaroni gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí.

16Olúwa sọ fún Mose pé, “Sọ fún Aaroni, ‘Na ọ̀pá rẹ jáde kí ó sì lu eruku ilẹ̀,’ jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti ni erùpẹ̀ ilẹ̀ yóò ti di kòkòrò-kantíkantí.” (Kòkòrò kan tí ó ní ìyẹ́ méjì tí ó ṣì ń ta ni.)

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.