Esekiẹli 27

Ní ìsinsin yìí tí Òkun fọ ọ túútúú nínú ibú omi; nítorí náà òwò rẹ àti gbogbo ẹgbẹ́ rẹ ní àárín rẹ, ni yóò ṣubú.

Ezekiel 27:34 (UKJV) In the time when you shall be broken by the seas in the depths of the waters your merchandise and all your company in the midst of you shall fall.

32Àti nínú arò wọn ni wọn yóò sì pohùnréré ẹkún fún ọ wọn yóò sì pohùnréré ẹkún sórí rẹ, wí pé: “Ta ni ó dàbí Tire èyí tí ó parun ní àárín Òkun?”

33Nígbà tí ọjà títà rẹ ti Òkun jáde wá ìwọ tẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lọ́rùn ìwọ fi ọrọ̀ tí ó pọ̀ àti àwọn ọjà títà rẹ sọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀.

34Ní ìsinsin yìí tí Òkun fọ ọ túútúú nínú ibú omi; nítorí náà òwò rẹ àti gbogbo ẹgbẹ́ rẹ ní àárín rẹ, ni yóò ṣubú.

35Ẹnu yóò ya gbogbo àwọn ti ń gbé ní erékùṣù náà sí ọ jìnnìjìnnì yóò bo àwọn ọba wọn, ìyọnu yóò sì han ní ojú wọn.

36Àwọn oníṣòwò láàrín àwọn orílẹ̀-èdè dún bí ejò sí ọ ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.