Esekiẹli 27

Ẹnu yóò ya gbogbo àwọn ti ń gbé ní erékùṣù náà sí ọ jìnnìjìnnì yóò bo àwọn ọba wọn, ìyọnu yóò sì han ní ojú wọn.

Ezekiel 27:35 (UKJV) All the inhabitants of the isles shall be astonished at you, and their kings shall be sore afraid, they shall be troubled in their countenance.

33Nígbà tí ọjà títà rẹ ti Òkun jáde wá ìwọ tẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lọ́rùn ìwọ fi ọrọ̀ tí ó pọ̀ àti àwọn ọjà títà rẹ sọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀.

34Ní ìsinsin yìí tí Òkun fọ ọ túútúú nínú ibú omi; nítorí náà òwò rẹ àti gbogbo ẹgbẹ́ rẹ ní àárín rẹ, ni yóò ṣubú.

35Ẹnu yóò ya gbogbo àwọn ti ń gbé ní erékùṣù náà sí ọ jìnnìjìnnì yóò bo àwọn ọba wọn, ìyọnu yóò sì han ní ojú wọn.

36Àwọn oníṣòwò láàrín àwọn orílẹ̀-èdè dún bí ejò sí ọ ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.