Esekiẹli 29

Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹ èmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹ gbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ. Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrín àwọn odò rẹ, àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.

Ezekiel 29:4 (UKJV) But I will put hooks in your jaws, and I will cause the fish of your rivers to stick unto your scales, and I will bring you up out of the midst of your rivers, and all the fish of your rivers shall stick unto your scales.

2“Ọmọ ènìyàn, kọjú sí Farao ọba Ejibiti kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i àti sí gbogbo Ejibiti.

3Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Èmi lòdì sí ọ, Farao ọba Ejibiti ìwọ ẹ̀mí búburú ńlá inú òkun tí ó dùbúlẹ̀ sí àárín àwọn odò ṣíṣàn rẹ. Èyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili; èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.”

4Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹ èmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹ gbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ. Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrín àwọn odò rẹ, àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.

5Èmi yóò sọ ọ́ nù sí aginjù ìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ: ìwọ yóò ṣubú sí gbangba oko a kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè. Èmi ti fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko igbó àti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ.

6Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ejibiti yóò mọ pé, Èmi ni Olúwa. “ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Israẹli.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.