Esekiẹli 32

Èmi yóò mú kí ìjọ ènìyàn rẹ kí ó tí ipa idà àwọn alágbára ènìyàn ṣubú àwọn orílẹ̀-èdè aláìláàánú jùlọ. Wọn yóò tú ìgbéraga Ejibiti ká, gbogbo ìjọ rẹ ní a yóò dá ojú wọn bolẹ̀.

Ezekiel 32:12 (UKJV) By the swords of the mighty will I cause your multitude to fall, the terrible of the nations, all of them: and they shall spoil the pomp of Egypt, and all the multitude thereof shall be destroyed.

10Èmi yóò mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn dẹ́rùbà ọ́, àwọn ọba wọn yóò sì wárìrì fún ìbẹ̀rù pẹ̀lú ìpayà nítorí rẹ, nígbà tí mo bá ju idà mi ní iwájú wọn. Ní ọjọ́ ìṣubú rẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wọn yóò wárìrì ní gbogbo ìgbà fún ẹ̀mí rẹ.

11“ ‘Nítorí èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Idà ọba Babeli yóò wá sí orí rẹ,

12Èmi yóò mú kí ìjọ ènìyàn rẹ kí ó tí ipa idà àwọn alágbára ènìyàn ṣubú àwọn orílẹ̀-èdè aláìláàánú jùlọ. Wọn yóò tú ìgbéraga Ejibiti ká, gbogbo ìjọ rẹ ní a yóò dá ojú wọn bolẹ̀.

13Gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ ni èmi yóò parun ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi kì i ṣe ẹsẹ̀ ènìyàn ní yóò tẹ ibẹ̀ ẹsẹ̀ ẹran ọ̀sìn kì yóò sì mú kí ibẹ̀ ni ẹrọ̀fọ̀.

14Lẹ́yìn náà èmi yóò mú kí omi rẹ̀ tòrò kí àwọn odò rẹ̀ kí o sàn bí epo, ni Olúwa Olódùmarè wí.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.